Iyanu nla: O pase ki won pon omi sinu l’adugbo (si ladugbo); Awon iranse se bi O ti wi, Jesu si so omi di waini, Opolopo eniyan si wariri (eeyan si wariri).
8. Jesu nikan ni ogba Getsemane, O gbadura si Olorun,
Oso fun Baba Re orun pe “Je k’ago yi re mi koja” (re mi koja); Sugbon ki i se gege bi mo ti fe, ife Baba orun ni k’a se, Jesu farada iku oro fun wa (farada ‘ku fun wa).
9. Jesu jiya lori oke Kalfari, O ta eje Re sile-
Fun ‘wenumo ese gbogbo iran Adamu eni-egbe (eni egbe); O ru gbogbo aisododo wa lo, O gbe ododo Tire wo wa, O so wa d’eni Ibukun Olorun (a d’eni Ibukun).
10. Olugbala ku iku oro lor’agbelebu fun eniyan,
Eni giga julo ni orun ku iku ti o to si wa (t’o to si wa); A da A lebi nitori ese wa, O ru idajo awa eda, Nipa ore-ofe, O da wa lare (a gba idalare).
11. Iyanu ni pe Olodumare bo ogo Re sile lorun,
O wa s’aye nitori ise igbala gbogbo araye (gbogbo aye); O yan lati ku tori ese wa, O fi iku Re segun iku, Ajinde Re fun wa ni iye orun (Iye ayeraye)
12. Jesu Oluwa ojo isimi ko d’ase aye wa duro,
O n fi oro we wa mo lojoojumo k’ale ye fun orun (ye fun orun); O n le ota wa seeyin, O n pese fun aini wa ni ojo gbogbo, E je ka f’ogo f’Olurapada wa (f’Olurapada wa).